21 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí nípa Áhábù ọmọ Koláyà àti nípa Sedekáyà ọmọ Maaseáyà, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi,+ ‘Wò ó, màá fi wọ́n lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, á sì pa wọ́n lójú yín.
23 nítorí pé wọ́n ti hùwà àìnítìjú ní Ísírẹ́lì,+ wọ́n ń bá aya ọmọnìkejì wọn ṣe àgbèrè, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ èké ní orúkọ mi, èyí tí mi ò pa láṣẹ fún wọn.+
“‘“Èmi ni Ẹni tí ó mọ̀, èmi sì ni ẹlẹ́rìí,”+ ni Jèhófà wí.’”