-
Jeremáyà 51:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Bábílónì jẹ́ ife wúrà ní ọwọ́ Jèhófà;
Ó mú kí gbogbo ayé mu àmupara.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 23:32-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
‘Ìwọ yóò mu nínú ife ẹ̀gbọ́n rẹ, ife tí inú rẹ̀ jìn, tó sì fẹ̀.+
Wọ́n á fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà, èyí tó kún inú ife náà.+
33 Ìwọ yóò mu àmuyó, ìbànújẹ́ yóò sì bò ọ́,
Wàá mu látinú ife ìbẹ̀rù àti ti ahoro,
Ife Samáríà ẹ̀gbọ́n rẹ.
34 Ìwọ yóò mu nínú rẹ̀, ìwọ yóò mu ún gbẹ,+ wàá sì máa họ àpáàdì rẹ̀ jẹ,
Ìwọ yóò sì fa ọmú rẹ ya.
“Torí èmi alára ti sọ̀rọ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.’
-
-
Náhúmù 3:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
Ta ló máa bá a kẹ́dùn?’
Ibo ni màá ti rí àwọn olùtùnú fún ọ?
-
-
Náhúmù 3:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ìwọ náà á mutí yó;+
Wàá lọ fara pa mọ́.
Wàá sì wá ibi ààbò lọ́dọ̀ ọ̀tá rẹ.
-