-
Diutarónómì 30:1-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí. 4 Ì báà jẹ́ ìpẹ̀kun ọ̀run ni àwọn èèyàn rẹ tú ká sí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa kó ọ jọ, á sì mú ọ pa dà wá + láti ibẹ̀.
-
-
1 Àwọn Ọba 8:47, 48Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
47 tí wọ́n bá ro inú ara wọn wò ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ,+ tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ,+ tí wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ pé kí o ṣojú rere sí àwọn ní ilẹ̀ àwọn tó mú wọn lẹ́rú,+ tí wọ́n sọ pé, ‘A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣàṣìṣe; a ti ṣe ohun búburú,’+ 48 tí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn+ àti gbogbo ara* wọn pa dà sọ́dọ̀ rẹ ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá tó kó wọn lọ sóko ẹrú, tí wọ́n sì gbàdúrà sí ọ ní ìdojúkọ ilẹ̀ tí o fún àwọn baba ńlá wọn àti ìlú tí o yàn àti ilé tí mo kọ́ fún orúkọ rẹ,+
-