-
Ìsíkíẹ́lì 1:19-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a lọ pẹ̀lú wọn, tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra sókè.+ 20 Wọ́n á lọ sí ibi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí, ìyẹn ibikíbi tí ẹ̀mí náà bá lọ. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* tún wà nínú àwọn àgbá náà. 21 Tí wọ́n bá ń lọ, àwọn àgbá náà máa ń tẹ̀ lé wọn; tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà tún wà nínú àwọn àgbá náà.
-