-
2 Àwọn Ọba 24:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ó kó gbogbo Jerúsálẹ́mù lọ sí ìgbèkùn, gbogbo ìjòyè,+ gbogbo jagunjagun tó lákíkanjú àti gbogbo oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú gbogbo oníṣẹ́ irin,*+ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) èèyàn ló kó lọ sí ìgbèkùn. Kò ṣẹ́ ku ẹnì kankan àfi àwọn aláìní ní ilẹ̀ náà.+ 15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.
-
-
Jeremáyà 24:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí àwọn ọ̀pọ̀tọ́ yìí ṣe dára, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe fi ojú tó dára wo àwọn ará Júdà tó wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo rán lọ kúrò ní ibí yìí sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.
-