11 Àmọ́, ó sọ pé: “Jáde, kí o sì dúró sórí òkè níwájú Jèhófà.” Sì wò ó! Jèhófà ń kọjá lọ,+ ẹ̀fúùfù ńlá tó lágbára ń ya àwọn òkè, ó sì ń fọ́ àwọn àpáta níwájú Jèhófà,+ àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ẹ̀fúùfù náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìmìtìtì ilẹ̀+ wáyé, àmọ́ Jèhófà kò sí nínú ìmìtìtì ilẹ̀ náà.