-
Dáníẹ́lì 4:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “‘Bí mo ṣe ń wo ìran tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, ẹni mímọ́, tó ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run.+ 14 Ó ké jáde pé: “Ẹ gé igi náà lulẹ̀,+ ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, ẹ gbọn àwọn ewé rẹ̀ dà nù, kí ẹ sì tú àwọn èso rẹ̀ ká! Kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì kúrò lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. 15 Àmọ́ ẹ fi kùkùté igi náà sílẹ̀ pẹ̀lú gbòǹgbò rẹ̀* nínú ilẹ̀, kí ẹ sì fi ọ̀já irin àti bàbà dè é láàárín koríko pápá. Ẹ jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i, kí ìpín rẹ̀ sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko láàárín ewéko ayé.+ 16 Kí ọkàn rẹ̀ yí pa dà kúrò ní ti èèyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, kí ìgbà méje+ sì kọjá lórí rẹ̀.+
-