48 Ọba wá gbé Dáníẹ́lì ga, ó fún un ní ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tó dáa, ó sì fi ṣe alákòóso lórí gbogbo ìpínlẹ̀ Bábílónì+ àti olórí àwọn aṣíwájú gbogbo amòye Bábílónì. 49 Bí Dáníẹ́lì sì ṣe béèrè, ọba yan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò+ láti máa bójú tó ìpínlẹ̀ Bábílónì, àmọ́ Dáníẹ́lì ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba.