-
Dáníẹ́lì 2:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Àwọn ará Kálídíà dá ọba lóhùn, wọ́n ní: “Kò sí ẹnì kankan ní ayé* tó lè ṣe ohun tí ọba ń béèrè, torí kò sí ọba ńlá tàbí gómìnà tó tíì béèrè irú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àlùfáà onídán, pidánpidán tàbí ará Kálídíà kankan. 11 Àmọ́ ohun tí ọba ń béèrè ṣòro gan-an, kò sí ẹnì kankan tó lè sọ ọ́ fún ọba àfi àwọn ọlọ́run, tí kì í gbé láàárín àwọn ẹni kíkú.”*
-