-
Dáníẹ́lì 3:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Ẹni tó ń kéde wá kígbe pé: “A pàṣẹ fún ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, 5 pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kó sì jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa jù ú sínú iná ìléru tó ń jó.”+
-