31 Ṣé o lè so àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Kímà,
Àbí o lè tú àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?+
32 Ṣé o lè kó àgbájọ ìràwọ̀ jáde ní àsìkò rẹ̀,
Àbí o lè darí àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33 Ṣé o mọ àwọn òfin tó ń darí ojú ọ̀run,+
Àbí o lè fipá mú kí ayé tẹ̀ lé àwọn àṣẹ wọn?