18 Wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gbìmọ̀ ibi sí Jeremáyà,+ nítorí òfin kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn àlùfáà, ìmọ̀ràn kò sì ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn amòye, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní kúrò lọ́dọ̀ àwọn wòlíì. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀rọ̀ burúkú sí i, kí a má sì fiyè sí ohun tó ń sọ.”