ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 34:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, 7 tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún,+ tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini,+ àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀,+ tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.”+

  • Àìsáyà 1:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “Ní báyìí, ẹ wá, ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa,” ni Jèhófà wí.+

      “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò,

      Wọ́n máa di funfun bíi yìnyín;+

      Bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò,

      Wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.

  • Àìsáyà 44:22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Màá nu àwọn àṣìṣe rẹ kúrò bíi pé mo fi ìkùukùu* nù ún,+

      Màá sì nu àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò bíi pé mo fi àwọsánmà tó ṣú bolẹ̀ nù ún.

      Pa dà sọ́dọ̀ mi, torí màá tún ọ rà.+

  • Jeremáyà 50:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 “Ní ọjọ́ yẹn àti ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí,

      “A ó wá ẹ̀bi Ísírẹ́lì kiri,

      Ṣùgbọ́n a kò ní rí ìkankan,

      A kò sì ní rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Júdà,

      Nítorí màá dárí ji àwọn tí mo jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù.”+

  • Dáníẹ́lì 9:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Àánú àti ìdáríjì jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ torí a ti ṣọ̀tẹ̀ sí i.+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́