12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+
16 “Màá wá èyí tó sọ nù,+ màá mú èyí tó rìn lọ pa dà wálé, màá fi aṣọ wé èyí tó fara pa, màá sì tọ́jú èyí tó rẹ̀ kó lè lágbára; àmọ́ èmi yóò pa èyí tó sanra àti èyí tó lágbára. Èmi yóò dá a lẹ́jọ́.”
21 “Kí o wá sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ, èmi yóò kó wọn jọ láti ibi gbogbo, èmi yóò sì mú wọn wá sórí ilẹ̀ wọn.+