-
Jeremáyà 39:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́. 6 Ọba Bábílónì ní kí wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀ ní Ríbúlà, ọba Bábílónì sì ní kí wọ́n pa gbogbo èèyàn pàtàkì Júdà.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó fọ́ ojú Sedekáyà, ó sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é kó lè mú un wá sí Bábílónì.+
-
-
Dáníẹ́lì 5:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ní tìrẹ, ọba, Ọlọ́run Gíga Jù Lọ gbé ìjọba fún Nebukadinésárì bàbá rẹ, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó sì fún un ní ògo àti ọlá ńlá.+ 19 Torí pé Ó jẹ́ kó di ẹni ńlá, gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà ń gbọ̀n rìrì níwájú rẹ̀.+ Ó lè pa ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ tàbí kó dá a sí, ó sì lè gbé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ga tàbí kó rẹ̀ ẹ́ wálẹ̀.+
-