-
Émọ́sì 1:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘“Nítorí ìdìtẹ̀ mẹ́ta àwọn ọmọ Ámónì+ àti nítorí mẹ́rin, mi ò ní yí ọwọ́ mi pa dà,
Nítorí wọ́n la inú àwọn aboyún Gílíádì kí wọ́n lè mú agbègbè tiwọn fẹ̀ sí i.+
14 Torí náà, màá sọ iná sí ògiri Rábà,+
Á sì jó àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run,
Ariwo á sọ ní ọjọ́ ogun,
Àti ìjì líle ní ọjọ́ ẹ̀fúùfù.
15 Ọba wọn á sì lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.’
-