-
Lúùkù 11:9-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Torí náà, mò ń sọ fún yín, ẹ máa béèrè,+ a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.+ 10 Torí gbogbo ẹni tó bá ń béèrè máa rí gbà,+ gbogbo ẹni tó bá ń wá kiri máa rí, gbogbo ẹni tó bá sì ń kan ilẹ̀kùn la máa ṣí i fún. 11 Ká sòótọ́, bàbá wo ló wà láàárín yín tó jẹ́ pé, tí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, ó máa fún un ní ejò dípò ẹja?+ 12 Tàbí tó bá tún béèrè ẹyin, tó máa fún un ní àkekèé? 13 Torí náà, tí ẹ̀yin bá mọ bí ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín ní ẹ̀bùn tó dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni burúkú ni yín, mélòómélòó wá ni Baba yín tó wà ní ọ̀run, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”+
-