-
Mátíù 17:10-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi í pé: “Kí ló wá dé tí àwọn akọ̀wé òfin fi ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 11 Ó fèsì pé: “Èlíjà ń bọ̀ lóòótọ́, ó sì máa mú kí gbogbo nǹkan pa dà sí bó ṣe yẹ.+ 12 Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé Èlíjà ti wá, wọn ò sì dá a mọ̀, àmọ́ wọ́n ṣe ohun tó wù wọ́n sí i.+ Lọ́nà kan náà, Ọmọ èèyàn máa jìyà lọ́wọ́ wọn.”+ 13 Ìgbà yẹn ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fòye mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jòhánù Arinibọmi ló ń bá àwọn sọ.
-