20 Ní ti èyí tó bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, òun ló ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tó sì fi ayọ̀ tẹ́wọ́ gbà á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 21 Síbẹ̀, kò ta gbòǹgbò nínú rẹ̀, àmọ́ ó ń bá a lọ fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni a mú un kọsẹ̀.