-
Máàkù 6:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ wá síbi tó dá ní ẹ̀yin nìkan, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.”+ Torí ọ̀pọ̀ ló ń wá, tí wọ́n sì ń lọ, wọn ò sì ní àkókò kankan tí ọwọ́ wọn dilẹ̀, kódà, wọn ò ráyè jẹun. 32 Torí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ síbi tó dá, tí àwọn nìkan máa wà.+ 33 Àmọ́ àwọn èèyàn rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ, ọ̀pọ̀ sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwọn èèyàn láti gbogbo ìlú sì fi ẹsẹ̀ sáré dé ibẹ̀ ṣáájú wọn.
-