-
Lúùkù 15:3-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Ó wá sọ àpèjúwe yìí fún wọn, ó ní: 4 “Ọkùnrin wo nínú yín, tó ní ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, ló jẹ́ pé tí ọ̀kan nínú wọn bá sọ nù, kò ní fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) yòókù sílẹ̀ nínú aginjù, kó sì wá èyí tó sọ nù lọ títí ó fi máa rí i?+ 5 Tó bá sì rí i, ó máa gbé e lé èjìká rẹ̀, inú rẹ̀ sì máa dùn. 6 Tó bá wá dé ilé, á pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, á sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀, torí mo ti rí àgùntàn mi tó sọ nù.’+ 7 Mò ń sọ fún yín pé, lọ́nà kan náà, inú àwọn tó wà ní ọ̀run máa dùn gan-an torí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà+ ju olódodo mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) tí kò nílò ìrònúpìwàdà.
-