-
Máàkù 10:2-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n fẹ́ dán an wò, wọ́n sì bi í bóyá ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.+ 3 Ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ni Mósè pa láṣẹ fún yín?” 4 Wọ́n sọ pé: “Mósè fàyè gba ká kọ ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”+ 5 Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Torí pé ọkàn yín le+ ló ṣe kọ àṣẹ yìí fún yín.+ 6 Ṣùgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá, ‘Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ 7 Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,+ 8 àwọn méjèèjì á sì di ara kan,’+ tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. 9 Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”+ 10 Nígbà tí wọ́n tún wà nínú ilé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí. 11 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè,+ ó ti da obìnrin náà, 12 tí obìnrin kan bá sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, lẹ́yìn tó kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, ó ti ṣe àgbèrè.”+
-