-
Lúùkù 19:36-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Bó ṣe ń lọ, wọ́n ń tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sí ojú ọ̀nà.+ 37 Gbàrà tó dé tòsí ojú ọ̀nà tó lọ sísàlẹ̀ láti Òkè Ólífì, inú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dùn, wọ́n sì gbóhùn sókè, wọ́n ń yin Ọlọ́run torí gbogbo iṣẹ́ agbára tí wọ́n ti rí, 38 wọ́n ń sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ bí Ọba ní orúkọ Jèhófà!* Àlàáfíà ní ọ̀run àti ògo ní ibi gíga lókè!”+
-