-
Máàkù 12:18-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 19 “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé tí arákùnrin ẹnì kan bá kú, tó sì fi ìyàwó sílẹ̀ àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.+ 20 Arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ nígbà tó kú, kò fi ọmọ kankan sílẹ̀. 21 Ẹnì kejì fẹ́ obìnrin náà, àmọ́ ọkùnrin náà kú láìbímọ, ohun kan náà ló sì ṣẹlẹ̀ sí ẹni kẹta. 22 Àwọn méjèèje ò fi ọmọ kankan sílẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. 23 Nígbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.”
-
-
Lúùkù 20:27-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Àmọ́ àwọn kan lára àwọn Sadusí, àwọn tó sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 28 “Olùkọ́, Mósè kọ̀wé fún wa pé, ‘Tí arákùnrin ọkùnrin kan bá kú, tó fi ìyàwó sílẹ̀, àmọ́ tí kò bímọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’+ 29 Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, àmọ́ ó kú láìbímọ. 30 Bákan náà ni ẹnì kejì 31 àti ẹnì kẹta náà fẹ́ ẹ. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn méjèèje; wọ́n kú láìfi ọmọ kankan sílẹ̀. 32 Níkẹyìn, obìnrin náà kú. 33 Tó bá wá dìgbà àjíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí àwọn méjèèje ló ti fi ṣe aya.”
-