-
Máàkù 13:21-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 “Bákan náà, tí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín nígbà yẹn pé, ‘Ẹ wò ó! Kristi wà níbí’ tàbí ‘Ẹ wò ó! Òun nìyẹn,’ ẹ má gbà á gbọ́.+ 22 Torí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké máa dìde,+ wọ́n sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu láti kó àwọn àyànfẹ́ pàápàá ṣìnà, tó bá ṣeé ṣe. 23 Torí náà, ẹ ṣọ́ra.+ Mo ti sọ gbogbo nǹkan fún yín ṣáájú.
-