-
Lúùkù 22:3-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Sátánì wá wọnú Júdásì, tí wọ́n ń pè ní Ìsìkáríọ́tù, tó wà lára àwọn Méjìlá náà,+ 4 ó sì lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa fà á lé wọn lọ́wọ́.+ 5 Èyí múnú wọn dùn gan-an, wọ́n sì gbà láti fún un ní owó fàdákà.+ 6 Torí náà, ó gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ìgbà tó máa dáa jù láti fà á lé wọn lọ́wọ́ níbi tí kò sí èrò.
-