-
Lúùkù 8:28-30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Bó ṣe rí Jésù, ó kígbe, ó sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀, ó wá ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Mo bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”+ 29 (Torí Jésù ti ń pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà pé kó jáde lára ọkùnrin náà. Ẹ̀mí náà ti gbá ọkùnrin náà mú lọ́pọ̀ ìgbà,*+ léraléra sì ni wọ́n fi ẹ̀wọ̀n àti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, tí wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, àmọ́ ó máa ń já àwọn ìdè náà, ẹ̀mí èṣù náà á sì mú kó lọ sí àwọn ibi tó dá.) 30 Jésù bi í pé: “Kí lorúkọ rẹ?” Ó sọ pé: “Líjíónì,” torí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí èṣù ti wọ inú rẹ̀.
-