-
Mátíù 14:1-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ní àkókò yẹn, Hẹ́rọ́dù, alákòóso agbègbè náà,* gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+ 2 ó sì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Jòhánù Arinibọmi nìyí. A ti jí i dìde, ìdí sì nìyẹn tó fi lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára yìí.”+ 3 Hẹ́rọ́dù* ti mú Jòhánù, ó dè é, ó sì fi sẹ́wọ̀n torí Hẹrodíà, ìyàwó Fílípì arákùnrin rẹ̀.+ 4 Jòhánù sì ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti fẹ́ obìnrin yìí.”+ 5 Àmọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó ń bẹ̀rù àwọn èèyàn, torí pé wòlíì ni wọ́n kà á sí.+
-
-
Lúùkù 9:7-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Hẹ́rọ́dù* alákòóso agbègbè náà* wá gbọ́ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ọkàn rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá torí àwọn kan ń sọ pé a ti jí Jòhánù dìde,+ 8 àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà ti fara hàn, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.+ 9 Hẹ́rọ́dù sọ pé: “Mo ti bẹ́ Jòhánù lórí.+ Ta wá ni ẹni tí mò ń gbọ́ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀?” Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí i.+
-