32 Nígbà tí wọ́n ń lọ, wò ó! àwọn èèyàn mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; 33 lẹ́yìn tó sì lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin náà sọ̀rọ̀.+ Ẹnu ya àwọn èrò náà, wọ́n sì sọ pé: “A ò tíì rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.”+
14 Lẹ́yìn náà, ó lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, èyí tí kò jẹ́ kí ẹnì kan lè sọ̀rọ̀.+ Lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí kò lè sọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀, ẹnu sì ya àwọn èrò tó wà níbẹ̀.+