-
Lúùkù 4:38, 39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Lẹ́yìn tó kúrò nínú sínágọ́gù, ó wọ ilé Símónì. Akọ ibà ń ṣe ìyá ìyàwó Símónì, wọ́n sì ní kó ràn án lọ́wọ́.+ 39 Torí náà, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin náà, ó sì bá ibà náà wí, ibà náà sì lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
-