-
Mátíù 24:15-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Torí náà, tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro, tó dúró ní ibi mímọ́, bí wòlíì Dáníẹ́lì ṣe sọ ọ́+ (kí òǹkàwé lo òye), 16 nígbà náà, kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.+ 17 Kí ẹni tó wà lórí ilé má sọ̀ kalẹ̀ wá kó ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀, 18 kí ẹni tó wà ní pápá má sì pa dà wá mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀. 19 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o! 20 Ẹ máa gbàdúrà kí ìgbà tí ẹ máa sá má lọ bọ́ sí ìgbà òtútù tàbí ọjọ́ Sábáàtì;
-
-
Lúùkù 21:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Àmọ́, tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ ogun pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká,+ nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tó máa dahoro ti sún mọ́lé.+ 21 Kí àwọn tó wà ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè,+ kí àwọn tó wà nínú ìlú náà kúrò níbẹ̀, kí àwọn tó sì wà ní ìgbèríko má wọ ibẹ̀, 22 torí pé àwọn ọjọ́ yìí la máa ṣe ìdájọ́,* kí gbogbo ohun tí a kọ lè ṣẹ. 23 Ó mà ṣe o, fún àwọn aláboyún àti àwọn tó ń tọ́ ọmọ jòjòló ní àwọn ọjọ́ yẹn o!+ Torí wàhálà ńlá máa bá ilẹ̀ náà, ìbínú sì máa wá sórí àwọn èèyàn yìí.
-