-
Lúùkù 22:10-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Tí ẹ bá ti wọnú ìlú náà, ọkùnrin kan tó ru ìṣà omi máa pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tó bá wọ̀.+ 11 Kí ẹ sì sọ fún ẹni tó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ ní ká bi ọ́ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, tí èmi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ti lè jẹ Ìrékọjá?”’ 12 Ọkùnrin yẹn sì máa fi yàrá ńlá kan hàn yín lókè, tó ti ní àwọn ohun tí a nílò. Ẹ ṣètò rẹ̀ síbẹ̀.” 13 Torí náà, wọ́n lọ, wọ́n rí i bó ṣe sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì múra sílẹ̀ fún Ìrékọjá.
-