9 Lẹ́yìn ìyẹn, bí Jésù ṣe ń kúrò níbẹ̀, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Mátíù, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Ló bá dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+
27 Lẹ́yìn náà, ó jáde lọ, ó sì rí agbowó orí kan tó ń jẹ́ Léfì, tó jókòó sí ọ́fíìsì àwọn agbowó orí, ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”+28 Ló bá fi ohun gbogbo sílẹ̀, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e.