-
Mátíù 4:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Síríà, wọ́n sì gbé gbogbo àwọn tí onírúurú àìsàn ń ṣe, tí wọ́n sì ń joró wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ pẹ̀lú àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu,+ àwọn tó ní wárápá + àti àrùn rọpárọsẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn. 25 Torí náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tẹ̀ lé e láti Gálílì, Dekapólì,* Jerúsálẹ́mù, Jùdíà àti láti òdìkejì Jọ́dánì.
-
-
Máàkù 3:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Àmọ́ Jésù kúrò níbẹ̀ lọ sí òkun, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láti Gálílì àti Jùdíà sì tẹ̀ lé e.+ 8 Kódà, nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbọ́ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣe, wọ́n wá bá a láti Jerúsálẹ́mù, Ídúmíà, òdìkejì Jọ́dánì àti agbègbè Tírè àti Sídónì.
-