ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 9:14, 15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá bá a, wọ́n sì bi í pé: “Kí ló dé tí àwa àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 15 Jésù sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó máa mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó ṣọ̀fọ̀ tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, àbí ó wà? Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀.

  • Máàkù 2:18-20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀. Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí máa ń gbààwẹ̀ àmọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 19 Jésù sọ fún wọn pé: “Tí ọkọ ìyàwó+ bá ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó, kò sí ohun tó máa mú kí wọ́n gbààwẹ̀, àbí ó wà? Tí ọkọ ìyàwó bá ṣì wà lọ́dọ̀ wọn, wọn ò lè gbààwẹ̀. 20 Àmọ́ ọjọ́ ń bọ̀, tí a máa mú ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n máa wá gbààwẹ̀ lọ́jọ́ yẹn.

  • Lúùkù 7:34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Ọmọ èèyàn wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, àmọ́ ẹ sọ pé: ‘Wò ó! Ọkùnrin alájẹkì, ti kò mọ̀ ju kó mu wáìnì lọ, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀!’+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́