6 Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì, ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+7 obìnrin kan tó ní orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sí orí rẹ̀ nígbà tó ń jẹun.*
3 Nígbà tó wà ní Bẹ́tánì, tó ń jẹun* ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀, obìnrin kan mú orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà sí wá, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an ni. Ó já orùba alabásítà náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sórí rẹ̀.+
3 Màríà wá mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan* òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an, ó dà á sí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ. Òórùn òróró onílọ́fínńdà náà wá gba inú ilé náà kan.+