12 Bó ṣe sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, wò ó! wọ́n ń gbé òkú ọkùnrin kan jáde, òun nìkan ṣoṣo ni ìyá rẹ̀ bí.+ Yàtọ̀ síyẹn, opó ni obìnrin náà. Èrò rẹpẹtẹ tún tẹ̀ lé e látinú ìlú náà. 13 Nígbà tí Olúwa tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é,+ ó sì sọ fún un pé: “Má sunkún mọ́.”+