ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 18:1-5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Ní wákàtí yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sí tòsí Jésù, wọ́n sì bi í pé: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?”+ 2 Torí náà, ó pe ọmọ kékeré kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó mú un dúró ní àárín wọn, 3 ó sì sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé ẹ yí pa dà,* kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé,+ ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run.+ 4 Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run;+ 5 ẹnikẹ́ni tó bá sì gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi gba èmi náà.

  • Máàkù 9:33-37
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 33 Lẹ́yìn náà, wọ́n dé sí Kápánáúmù. Nígbà tó wà nínú ilé, ó bi wọ́n léèrè pé: “Kí lẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?”+ 34 Wọn ò sọ̀rọ̀, torí wọ́n ń jiyàn láàárín ara wọn lójú ọ̀nà nípa ẹni tó tóbi jù. 35 Torí náà, ó jókòó, ó pe àwọn Méjìlá náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, òun ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránṣẹ́ gbogbo yín.”+ 36 Ó wá mú ọmọ kékeré kan, ó mú un dúró ní àárín wọn; ó fi ọwọ́ gbá a mọ́ra, ó sì sọ fún wọn pé: 37 “Ẹnikẹ́ni tó bá gba irú ọmọ kékeré+ yìí nítorí orúkọ mi gba èmi náà; ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí, kì í ṣe èmi nìkan ló gbà, àmọ́ ó tún gba Ẹni tó rán mi.”+

  • Lúùkù 22:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Àmọ́, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn gidigidi nípa ẹni tí wọ́n kà sí ẹni tó tóbi jù nínú wọn.+

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́