-
Jémíìsì 4:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ pé: “Lónìí tàbí lọ́la, a máa rìnrìn àjò lọ sí ìlú yìí, a máa lo ọdún kan níbẹ̀, a máa ṣòwò, a sì máa jèrè,”+ 14 bẹ́ẹ̀ sì rèé, ẹ ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí yín lọ́la.+ Torí ìkùukùu ni yín, tó máa ń wà fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà tí á pòórá.+ 15 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ sọ pé: “Tí Jèhófà* bá fẹ́,+ a máa wà láàyè, a sì máa ṣe tibí tàbí tọ̀hún.” 16 Àmọ́ ẹ̀ ń gbéra ga, ẹ sì ń fọ́nnu. Gbogbo ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀ burú.
-