-
Mátíù 19:16-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Wò ó! ẹnì kan wá bá a, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 17 Ó sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kan ló wà.+ Àmọ́ o, tí o bá fẹ́ jogún ìyè, máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.”+ 18 Ó bi í pé: “Àwọn àṣẹ wo?” Jésù sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ 19 bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ+ àti pé, kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 20 Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ fún un pé: “Mo ti ń ṣe gbogbo nǹkan yìí; kí ló kù tí mi ò tíì ṣe?” 21 Jésù sọ fún un pé: “Tí o bá fẹ́ jẹ́ pípé,* lọ ta àwọn ohun ìní rẹ, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run;+ kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà gbọ́ èyí, ó fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+
-
-
Máàkù 10:17-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Bó ṣe ń lọ, ọkùnrin kan sáré wá, ó sì kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, ó bi í pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 18 Jésù sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.+ 19 O mọ àwọn àṣẹ náà pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ o ò gbọ́dọ̀ lu jìbìtì,+ bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”+ 20 Ọkùnrin náà sọ fún un pé: “Olùkọ́, gbogbo nǹkan yìí ni mo ti ń ṣe láti ìgbà ọ̀dọ́ mi.” 21 Jésù wò ó, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó wá sọ fún un pé, “Ohun kan wà tí o ò tíì ṣe: Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 22 Àmọ́ inú ọkùnrin náà ò dùn torí èsì tó fún un, ó sì fi ìbànújẹ́ kúrò, torí ohun ìní rẹ̀ pọ̀.+
-
-
Lúùkù 10:25-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Wò ó! ọkùnrin kan tó mọ Òfin dunjú dìde láti dán an wò, ó sì sọ pé: “Olùkọ́, kí ló yẹ kí n ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 26 Ó sọ fún un pé: “Kí la kọ sínú Òfin? Kí lo kà níbẹ̀?” 27 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ,’+ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’”+ 28 Ó sọ fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; máa ṣe bẹ́ẹ̀, o sì máa rí ìyè.”+
-