2 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà+ ń bọ̀ bí olè ní òru.+ 3 Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn,+ bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà.