29 “O ò gbọ́dọ̀ lọ́ra láti mú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko rẹ àti ohun tó kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú àwọn ibi ìfúntí* rẹ láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí o fún mi ní àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ.+
13 Torí tèmi+ ni gbogbo àkọ́bí. Lọ́jọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ mo ya gbogbo àkọ́bí ní Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara mi, látorí èèyàn dórí ẹranko.+ Wọ́n á di tèmi. Èmi ni Jèhófà.”
17 Torí tèmi ni gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko.+ Ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni mo yà wọ́n sí mímọ́ fún ara mi.