ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Mátíù 26:69-75
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 69 Pétérù jókòó síta nínú àgbàlá, ìránṣẹ́bìnrin kan sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!”+ 70 Àmọ́ ó sẹ́ níwájú gbogbo wọn, ó ní: “Mi ò mọ ohun tí ò ń sọ.” 71 Nígbà tó jáde lọ sí ilé ẹnu ọ̀nà, ọmọbìnrin míì tún kíyè sí i, ó sì sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì.”+ 72 Ló bá tún sẹ́, ó sì búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” 73 Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró sí àyíká wá, wọ́n sì sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé ìwọ náà wà lára wọn, torí ká sòótọ́, èdè ẹnu rẹ* tú ọ fó.” 74 Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ. 75 Pétérù wá rántí ohun tí Jésù sọ, pé: “Kí àkùkọ tó kọ, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.

  • Máàkù 14:66-72
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 66 Nígbà tí Pétérù wà nísàlẹ̀ nínú àgbàlá, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà wá.+ 67 Bó ṣe rí Pétérù tó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó sì sọ pé: “Ìwọ náà wà pẹ̀lú Jésù ará Násárẹ́tì yìí.” 68 Àmọ́ ó sẹ́, ó ní: “Mi ò mọ̀ ọ́n, ohun tí ò ń sọ ò sì yé mi,” ló bá jáde lọ sí ibi àbáwọlé.* 69 Ìránṣẹ́bìnrin náà rí i níbẹ̀, ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn tó dúró nítòsí pé: “Ọ̀kan lára wọn nìyí.” 70 Ó tún ń sẹ́. Lẹ́yìn tó ṣe díẹ̀, àwọn tó dúró nítòsí tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún Pétérù pé: “Ó dájú pé o wà lára wọn, torí ká sòótọ́, ará Gálílì ni ọ́.” 71 Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Mi ò mọ ọkùnrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí!” 72 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ kọ lẹ́ẹ̀kejì,+ Pétérù sì rántí ohun tí Jésù sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, o máa sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+ Ló bá bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.

  • Jòhánù 18:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 Àwọn ẹrú àti àwọn òṣìṣẹ́ dúró yí ká iná èédú tí wọ́n dá, torí pé òtútù mú, wọ́n sì ń yáná. Pétérù náà dúró síbẹ̀, ó sì ń yáná.

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́