7 Síbẹ̀, òótọ́ ni mò ń sọ fún yín, torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà+ ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín.
17 ‘“Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Ọlọ́run wí, “èmi yóò tú lára ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn,* àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò máa rí ìran, àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò sì máa lá àlá,+