16 “Torí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni,+ kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+
19 Torí náà, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Ọmọ ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀, àfi ohun tó bá rí tí Baba ń ṣe nìkan.+ Torí ohunkóhun tí Ẹni yẹn bá ṣe, àwọn nǹkan yìí ni Ọmọ náà ń ṣe lọ́nà kan náà.
30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+