24 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tó sì gba Ẹni tó rán mi gbọ́, ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ a ò sì ní dá a lẹ́jọ́, àmọ́ ó ti tinú ikú bọ́ sínú ìyè.+
17Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ó gbójú sókè wo ọ̀run, ó sọ pé: “Baba, wákàtí náà ti dé. Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo,+2 bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,*+ kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un+ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+