41 Ó wá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sí ìwọ̀n ibi tí òkúta lè dé tí wọ́n bá jù ú látọ̀dọ̀ wọn, ó kúnlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, 42 ó ní: “Baba, tí o bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Àmọ́, ìfẹ́ rẹ ni kó ṣẹ, kì í ṣe tèmi.”+
7 Nígbà tí Kristi wà ní ayé,* ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì fi ẹkún tó rinlẹ̀ àti omijé tọrọ+ lọ́wọ́ Ẹni tó lè gbà á lọ́wọ́ ikú, a sì gbọ́ ọ, a ṣojúure sí i torí pé ó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.