25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún un,+26 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, kí ó fi omi wẹ̀ ẹ́ mọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,+
23 Kí Ọlọ́run àlàáfíà fúnra rẹ̀ sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí ẹ̀mí àti ọkàn* àti ara ẹ̀yin ará, tó dára ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ aláìlẹ́bi nígbà tí Olúwa wa Jésù Kristi bá wà níhìn-ín.+
13 Síbẹ̀, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́, torí pé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín+ fún ìgbàlà nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di mímọ́+ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́.
22 Ní báyìí tí ẹ ti fi ìgbọràn yín sí òtítọ́ wẹ ara yín* mọ́, tí èyí sì mú kí ẹ ní ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn,+ kí ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara yín látọkàn wá.+