9 wọ́n dé látibi ibojì náà, wọ́n sì ròyìn gbogbo nǹkan yìí fún àwọn Mọ́kànlá náà àti gbogbo àwọn yòókù.+ 10 Àwọn obìnrin náà ni Màríà Magidalénì, Jòánà àti Màríà ìyá Jémíìsì. Bákan náà, àwọn obìnrin yòókù tó wà pẹ̀lú wọn ń sọ àwọn nǹkan yìí fún àwọn àpọ́sítélì.