-
Mátíù 27:5-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Torí náà, ó da àwọn ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, ó sì kúrò níbẹ̀. Ó wá lọ pokùn so.+ 6 Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà kó àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì sọ pé: “Kò bófin mu ká kó o sí ibi ìṣúra mímọ́, torí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7 Lẹ́yìn tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fi owó náà ra pápá amọ̀kòkò, kí wọ́n lè máa sin àwọn àjèjì síbẹ̀. 8 Torí náà, Pápá Ẹ̀jẹ̀+ ni wọ́n ń pe pápá náà títí dòní yìí.
-